Numbers 26:4-50

4“Ka iye àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ọmọ-ogun (20) ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.”

Èyí ni àwọn ọmọ Israẹli tí ó jáde láti Ejibiti wá:

5 aÀwọn ọmọ Reubeni, àkọ́bí ọmọkùnrin Israẹli,
láti ẹni ti ìdílé Hanoku, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé Hanoku ti jáde wá;
Láti ìdílé Pallu, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé àwọn ọmọ Pallu ti jáde wá;
6ti Hesroni, ìdílé àwọn ọmọ Hesroni;
ti Karmi, ìdílé àwọn ọmọ Karmi.
7Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Reubeni; àwọn tí a sì kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlélógún ó-lé-ẹgbẹ̀sán ó-dínàádọ́rin (43,730).
8Àwọn ọmọkùnrin Pallu ni Eliabu, 9àwọn ọmọkùnrin Elifelehu ni Nemueli àti Eliabu, Datani àti Abiramu. Èyí ni Datani àti Abiramu náà tí wọ́n ní òkìkí nínú ìjọ tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí Mose àti Aaroni tí ó sì wà lára àwọn ẹgbẹ́ Kora nígbà tí wọ́n bá Olúwa jà. 10Ilẹ̀ sì la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé wọn mì pọ̀ pẹ̀lú Kora, nígbà tí ẹgbẹ́ rẹ̀ kú níbi tí iná ti run àwọn àádọ́tà-lé-nígba ọkùnrin (250). Tí wọ́n sì di ààmì ìkìlọ̀. 11Àwọn ọmọ Kora, bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò kú.

12Àwọn ọmọ ìran Simeoni bí ìdílé wọn:
ti Nemueli, ìdílé Nemueli;
ti Jamini, ìdílé Jamini;
ti Jakini, ìdílé Jakini;
13ti Sera, ìdílé Sera;
tí Saulu, ìdílé Saulu.
14Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Simeoni, ẹgbàá-mọ́kànlá ó-lé-igba. (22,200) ọkùnrin.

15Àwọn ọmọ Gadi bí ìdílé wọn:
ti Sefoni, ìdílé Sefoni;
ti Haggi, ìdílé Haggi;
ti Ṣuni, ìdílé Ṣuni;
16ti Osni, ìdílé Osni;
ti Eri, ìdílé Eri;
17ti Arodi, ìdílé Arodi;
ti Areli, ìdílé Areli.
18Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gadi tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500).

19Àwọn ọmọ Juda ni Eri àti Onani, ṣùgbọ́n Eri àti Onani kú ní ilẹ̀ Kenaani.
20Àti àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:
ti Ṣela, ìdílé Ṣela;
ti Peresi, ìdílé Peresi;
ti Sera, ìdílé Sera.
21Àwọn ọmọ Peresi:
ti Hesroni, ìdílé Hesroni;
ti Hamulu, ìdílé Hamulu.
22Wọ̀nyí ni ìdílé Juda; gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá-méjì-dínlógójì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (76,500).

23Àwọn ọmọ Isakari gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:
ti Tola, ìdílé Tola;
ti Pufa, ìdílé Pufa;
24ti Jaṣubu, ìdílé Jaṣubu;
ti Ṣimroni, ìdílé Ṣimroni.
25Wọ̀nyí ni ìdílé Isakari gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá-méjìlélọ́gbọ̀n ó-lé-ọ̀ọ́dúnrún (64,300).

26Àwọn ọmọ Sebuluni gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:
ti Seredi, ìdílé Seredi;
ti Eloni, ìdílé Eloni;
ti Jaleeli, ìdílé Jaleeli.
27Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Sebuluni gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (60,500).

28Àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; Manase àti Efraimu:
29Àwọn ọmọ Manase:
ti Makiri, ìdílé Makiri (Makiri sì bí Gileadi);
ti Gileadi, ìdílé àwọn ọmọ Gileadi.
30Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gileadi:
ti Ieseri, ìdílé Ieseri;
ti Heleki, ìdílé Heleki
31àti ti Asrieli, ìdílé Asrieli;
àti ti Ṣekemu, ìdílé Ṣekemu;
32àti Ṣemida, ìdílé àwọn ọmọ Ṣemida;
àti ti Heferi, ìdílé àwọn ọmọ Heferi.
33(Ṣelofehadi ọmọ Heferi kò sì ni ọmọkùnrin, bí kò ṣe ọmọbìnrin; orúkọ àwọn ọmọbìnrin ni Mahila, Noa, àti Hogla, Milka àti Tirsa).
34Wọ̀nyí ni ìdílé Manase tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (52,700).
35Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Efraimu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:
láti ọ̀dọ̀ Ṣutelahi, ìdílé àwọn ọmọ Ṣutelahi;
ti Bekeri, ìdílé àwọn ọmọ Bekeri;
ti Tahani, ìdílé àwọn ọmọ Tahani.
36Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ṣutelahi:
ti Erani, ìdílé àwọn ọmọ Erani;
37Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Efraimu, àwọn tí a kà nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìn-dínlógún ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (32,500).
Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.

38Àwọn ọmọ Benjamini gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn nìyìí:
tí Bela, ìdílé àwọn ọmọ Bela;
ti Aṣbeli, ìdílé àwọn ọmọ Aṣbeli;
ti Ahiramu, ìdílé àwọn ọmọ Ahiramu;
39ti Ṣufamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣufamu;
ti Hufamu, ìdílé àwọn ọmọ Hufamu.
40Àwọn ọmọ Bela ní ipasẹ̀ Ardi àti Naamani nìyìí:
ti Ardi, ìdílé àwọn ọmọ Ardi;
ti Naamani, ìdílé àwọn ọmọ Naamani.
41Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Benjamini; gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; àti àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-méjìlélógún ó-lé-ẹgbẹ̀jọ (45,600).

42Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dani gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:
ti Ṣuhamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣuhamu
Wọ̀nyí ni ìdílé Dani gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:
43Gbogbo ìdílé àwọn ọmọ Ṣuhamu, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-méjìlélọ́gbọ̀n ó-lé-irínwó (64,400).

44Ti àwọn ọmọ Aṣeri gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:
ti Imina, ìdílé àwọn ọmọ Imina;
ti Iṣfi, ìdílé àwọn ọmọ Iṣfi;
ti Beriah, ìdílé àwọn ọmọ Berii;
45Ti àwọn ọmọ Beriah:
ti Heberi, ìdílé àwọn ọmọ Heberi;
ti Malkieli, ìdílé àwọn ọmọ Malkieli.
46(Orúkọ ọmọ Aṣeri obìnrin nì jẹ́ Sera.)
47Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Aṣeri gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó-lé-egbèje (53,400).

48Ti àwọn ọmọ Naftali gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:
ti Jasieli, ìdílé àwọn ọmọ Jaseeli:
ti Guni, ìdílé àwọn ọmọ Guni;
49ti Jeseri, ìdílé àwọn ọmọ Jeṣeri;
ti Ṣillemu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣillemu.
50Wọ̀nyí ni ìdílé ti Naftali gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-méjìlélógún ó-lé-egbèje (45,400).
Copyright information for YorBMYO